Oro Olorun yi gba wa ni iyanju nipa idaniloju ati ere to wa ninu ka jise ihinrere fun gbogbo eniyan. O toka si iyato to wa ninu jije ati mimu ninu ile omo alaafia ati ile omo ti ko si alaafia. O ran wa leti, ikilo pataki to wa nipa sisi lati ile de ile (Luke 10: 3-9). Mo gbaa ni adura pe, ohunkohun to n de wa lona nipase ise isin wa si Olorun; Ogun to duro bi ti igba balogun ijoba Persia ati Danieli (Daniel 10: 12-13) ti ko fe ki n ri ere adura; Ogun to leri wipe oro Olorun ki yio wa si imuse lori aiye mi, mo pa a lase, e gbina ni oruko Jesu Kristi (Hebrews 12: 29). Nitori, a ko o wipe, omo ALASE ni mi, emi yio pase ohun kan, a o si fi idi re mule, imole yio si tan si ona mi Job 22: 28.